Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 474

Ọlọrun, ran imọlẹ Rẹ

Heavenly Father, send your light

Meter C.M (8.6.8.6) Orin Omode
  1. mp Ọlọrun, ran imọlẹ Rẹ,
    Si awa ọmọ Rẹ;
    K’ awa lè sìn k’ a si fẹ Ọ
    Lat’ ewe tit’ opin.

  2. p Awa dẹṣẹ, a si fọju,
    A nrìn l’ ọnà ‘parun;
    L’ ọkàn, ati n’ ìwa l’ a fi
    Jẹ́ ọta Ọlọrun.

  3. Ṣugbọn ọrẹ́ at’ olutọ,
    Nwọn nkó wa n’ ijanu;
    Nwọn nkọ́ wa, k’ a wá oju Rẹ,
    T’ a kò lè wá l’ asan.

  4. A gb’ oju wa s’ ori okè,
    Nib ‘gbala ti nwá;
    f ‘Wọ Orùn Ododo, dide,
    Lati m’ ara wa yá.

  5. f Dide, ràn s’ aiye oṣi yi,
    Ma ràn titi aiye !
    Titi awa o fi dàgba,
    Ma f’ọnà Kristian hàn. Amin.