Orin 473
Mo fẹ gbọ itan kanna
I love to hear the story which angel voices tell
- mf Mo fẹ gbọ itan kanna
T’ awọn angẹli nsọ;
di Bi Ọba Ogo ti wá
Gbe aiye oṣi yi;
p Bi mo tilẹ j’ẹlẹṣẹ,
cr Mo mọ̀ eyi daju,
f Pe Oluwa wa gbà mi,
‘Tori O fẹ mi bẹ. - mf Mo yọ̀ pe Olugbala
Ti jẹ ọmọde ri;
Lati fi ọna mimọ
Hàn awọn ọmọ Rẹ̀;
Bi emi ba si tẹle
Ipasẹ Rẹ̀ nihin,
On kò ni gbagbe mi lai,
‘Tori O fẹ mi bẹ. - f Ifẹ ati anu Rẹ̀,
Y’o jẹ orin fun mi;
B’emi kò tilẹ le ri,
Mo mọ pe, O ngbọ mi:
O si ti ṣe ileri,
Pe, mo le lọ kọrin
Larin awọn angẹli,
‘Tori O fẹ mi bẹ. Amin.