Orin 472
Jehofa ! Ọlọrun ogo
Jehovah, the Lord of Glory
- mf Jehofa ! Ọlọrun ogo,
Jẹ ki ọmọde yìn Ọ;
p A wolẹ̀ n’ irẹlẹ̀ fun Ọ,
Ore Rẹ ni orin wa.
Ogun Seraf dapọ gberin
Ifẹ Rẹ l’oke ọrun;
Ọlọrun ogo, gbọ́ tiwa,
B’ a ti nyin orukọ Rẹ. - Emmanuel ! Iwọ t’a bi,
p T’ a si fi kọ or’ igi,
O pe ọmọde kekere,
Lati wá si ọdọ Rẹ;
Oluwa, ‘b’ o ti pè, a de,
Jẹ k’ a ri anu Rẹ gbà !
K’ awa, pel’ awọn ọmọ Rẹ,
K’ a sin Ọ, k’ a si fẹ Ọ. - A ba lè wà, k’ a si fẹ Ọ,
K’ a si bẹ̀ru Rẹ l’ aiye;
Nikẹhin, k’ a wà pẹlu Rẹ,
f K a ri Ọ, k’ a si yìn Ọ.
Jesu Ọlọrun itunu,
Olori ọrẹ́ ! dide,
f Fi igbala Rẹ bukun wa.
Jọ tẹwọgba orin wa. Amin.