Orin 138
‘Ranṣẹ Ọlọrun, ẹ ma kede Rẹ̀
Ye servants of God, your Master proclaim
- f ‘Ranṣẹ Ọlọrun, ẹ ma kede Rẹ̀,
Ẹ ma k’ okiki orukọ Rẹ nla;
Ẹ gbe orukọ Jesu aṣẹgun ga,
Ijọba Rẹ̀ l’ogo lor’ohun gbogbo. - Olodumare, O njọba loke,
O si sunmọ wa, O mbẹ lọdọ wa;
Ijọ nla nì y’o kọrin iṣẹgun Rẹ̀,
O njewọ pe, ti Jesu ni igbala. - Igbala ni t’Ọlọrun t’ o gunwà !
Gbogb’ aiye kigbe, ẹ f’ọla f’Ọmọ,
di Iyìn Jesu ni gbogbo Angẹli nke,
p N’idojubole, nwọn nsin Ọdagutan. - f Ẹ jẹ k’awa sin, k’a f’ iyìn Rẹ̀ fun,
Ogo, agbara, ọgbọn at’ ipá,
Ọla at’ibukun, pẹl’ awọn Angẹl,
Ọpẹ́ ti kò lopin at’ ifẹ titi. Amin.