Orin 137
Wi jade larin keferi p’Oluwa l’Ọba
Tell it out among the nations that the Lord is King;
- Wi jade larin keferi p’Oluwa l’Ọba,
Wi jade ! Wi jade !
Wi jade f’orilẹ-ee, mu ki nwọn kọrin,
Wi jade! Wi jade !
cr Wi jade tiiyìntiyìn pe, On o ma pọ̀ si,
Pe, Ọba nla Ologo l’ Ọba alafia;
ff Wi jade tayọ̀tayọ̀, bi ìji tile nja,
Pe, O joko lor’ iṣàn omi, Ọba wa titi lai. - p Wi jade larin keferi pe, Jesu njọba,
Wi jade! Wi jade !
Wi jade f’orilẹ-ede, mu k’ide wọn ja,
Wi jade! Wi jade !
Wi jade fun awọn ti nsọokun, pe Jesu yè:
Wi jade f’alarẹ pe, O nfun ni nisimi;
Wi jade f’ẹlẹṣẹ pe, O wá lati gbàla;
Wi jade fun awọn ti nkú pe, O ti ṣẹgun ikun. - f Wi jade larin keferi, Krist njọba loke,
Wi jade! Wi jade !
Wi jade fun keferi, Ifẹ n’ ijọba Rẹ̀,
Wi jade! Wi jade !
cr Wi jade lọnà opópo, l’ abuja ọ̀na.
Jẹ k’o dùn jakejado ni gbogbo agbaiye:
ff B’i ró omi pupọ ni k’ iho ayọ̀ wa jẹ,
Titi gbohun-gbohun y’o fi gbe iró na de ‘kangun aiye. Amin.