Orin 139
Iyin f’Ẹni Mimọ julọ
Praise to the Holiest in the height
- f Iyin f’Ẹni Mimọ julọ,
Loke ati n’ilẹ;
Ọrọ Rẹ̀ gbogbo je iyanu,
Gbogb’ ọna Rẹ̀ daju/ - mf Ọgbọn Ọlọrun ti pọ to!
p Gbat’enia ṣubu;
cr Adam keji wá s’oju ‘ja,
f Ati lati gbàla. - mf Ọgbọn ifẹ! P’ẹran ara
p T’ o gbe Adam ṣubu,
cr Tun b’ọta ja ija ọtun,
f K’ o jà k’o si ṣẹgun. - mf Ati p’ẹbùn t’o j’ or’ọfẹ,
Sọ ara di ọtun;
p Ọlọrun papa Tikarẹ̀
J’Ọlọrun ninu wa. - Ifẹ ‘yanu! Ti Ẹniti
O pa ọta enia,
Ninu àwọ awa enia
Jẹ irora f’enia. - Nikọkọ ninu ọgba ni,
Ati lori igi,
To si kọ́ wa lati jiya,
To kọ́ wa lati kú. - f Iyin f’Ẹni Mimọ julọ,
Loke ati n’ile;
Ọrọ Rẹ gbogbo jẹ ‘yanu,
Gbogb’ ọ̀na Rẹ̀ daju. Amin.