Orin 136
Krist’, ki ‘jọba Rẹ de
Thy kingdom come, O God!
- mf Krist’, ki ‘jọba Rẹ de,
Ki aṣẹ Rẹ bẹrẹ;
F’ ọpa-irin Rẹ fọ
Gbogbo ipá ẹṣẹ. - p Ijọba ifẹ dà,
Ati t’alafia?
Gbawo ni irira
Yio tan bi t’ọrun? - Akoko na ha dà
T’ọtẹ yio pari,
Ikà at’ irẹjẹ,
Pẹlu ifẹkufẹ? - mf Oluwa jọ, dide,
Wá n’nu agbara Rẹ;
Fi ayọ fun awa
Ti o nṣafẹri Rẹ. - p Ẹda ngàn okọ Rẹ,
Kokò njẹ agbo Rẹ;
Iwa ‘tiju pupọ̀
Nfihàn pe ‘fẹ tutu. - Okùn bolẹ sibẹ̀,
Ni ilẹ keferi:
cr Dide ‘Rawọ orọ̀
ff Dide, maṣe wọ̀ mọ́. Amin