Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 135

Gbọ iró ẹfufu, lat’ ọna jijin

Hark! the swelling breezes, rising from afar

Meter 11.11.11.11 Ifihan, Mission
  1. mf Gbọ iró ẹfufu, lat’ ọna jijin;
    cr O nsọrọ jakadi ti ogun mimọ;
    f Ọlọrun mbẹ fun wa, O ti sọrọ Rẹ̀,
    O si nṣọ́ gbogbo nyin, “Ojiṣẹ ọrun.”

  2. ff Lọ! ‘wọ Ihinrere, ma ṣẹgun titi
    Okunkun ndimọlẹ , ni gbogbo aiye;
    Oṣa nwolẹ fun Ọ, ile wọn si nwó,
    Gbogb’ ẹda bù jẹwọ pe, ‘Wọ l’ Oluwa.

  3. mf Olugbala mimọ́ ti njọba loke,
    K’ awọn ọm’ ogun Rẹ ma ri Ọ titi;
    cr Jẹ k’ ọrọ Rẹ ma tàn lat’ ilẹ de ‘lẹ,
    ff Ki gbogbo agbaiye tẹriba fun Ọ. Amin.