Orin 113
Irawọ wo l’eyi?
Behold, what star is this
- f Irawọ wo l’eyi?
Wò b’o ti dara to,
Amọnà awọn keferi
S’ọdọ Ọba ogo. - Wò awọn amoye
Ti ila-orùn wá;
Nwọn wá fi ori balẹ fun
Jesu Olubukun. - Imọlẹ ti Ẹmi.
p Má ṣai tan n’ ilu wa;
Fi ọ̀na han wa k’ a le tọ,
Emmanueli wá. - f Gbogbo irun-malẹ̀,
Ati igba-malẹ̀,
Ti a mbọ n’ ilẹ keferi,
K’ o yàgo fun Jesu. - mf Ki gbogbo Abọrẹ̀
Ti mbẹ ni Afrika.
Jẹ amoye li otitọ,
Ki nwọn gb’ẹbọ Jesu. - Baba Ẹlẹda wa,
Ti o fi Jesu hàn
Awọn keferi igbani;
Fi hàn fun wa pẹlu. Amin.