Orin 114
Alafia fun Jesu
Hail to the Lord’s anointed,
- f Alafia fun Jesu
Ọmọ nla Dafidi
Ni akoko ti a yan
N’ ijọba Rẹ bẹrẹ̀;
O de lati tán iya,
Lati tú igbekun,
Lati mù ẹ̀ṣẹ kuro,
Y’o jọba laiṣegbe. - Arab, alarinkiri,
Yio wolẹ̀ fun u;
Alejo Etiopi,
Yio wá w’ogo Rẹ́:
Ọkọ̀ okun o pade
Pẹlu ọrẹ ìsin;
Lati f’ iṣura omi
Jọsìn lab’ẹsẹ̀ Rẹ̀. - Ọba yio wolẹ fùn
T’ awọn ti turari;
Gbogbo orilẹ-ede,
Yio si ma yìn i.
Ọkọ̀ okun y’o pade,
Pẹlu ọrẹ isin;
Lati f’ iṣura omi
Juba niwaju Rẹ̀. - mf L’ ojojumọ l’ adura
Yio ma goke lọ;
Ijọba Rẹ̀ y’o mà pọ̀
Ijọba ailopin:
Yo’ ṣẹgun gbogbo ọta
Y’o joko n ‘itẹ Rẹ̀;
Ogo Rẹ̀ yio ma ran
Alabukun lailai. Amin.