Orin 112
Gbọ ! orin ti Jubeli
Hark! the song of jubilee
- f Gbọ ! orin ti Jubeli,
O dabi sisán ará;
Tabi bi kikún okun
Gbat’ igbì rẹ̀ ba nlù ‘lẹ
ff Halleluia! Ọlọrun
Olodumare jọba;
ff Halleluia ! k’ ọ̀rọ na
Dún yi gbogbo aiye kà. - f Halleluia !—gbọ iró,
Lati aiye de ọrun,
Nji orin gbogbo ẹda,
L’oke, nisalẹ, yika,
Wo, Jehofa ti ẹtẹ̀
p Ida w’akọ̀; -- o paṣẹ,
Awọn ijọba aiye
Di ijọba Ọmọ Rẹ̀. - Y’o jọba yi aiye ka,
Pẹlu agbara nlanla;
Y’o jọba ‘gbati ọrun,
At’ aiye ba kọja lọ;
p Opin de: lab’ ọpa Rẹ̀.
pp L’ọtan enia ṣubu:
ff Halleluia ! Ọlọrun
Ni gbogbo l’ohun gbogbo. Amin.