Orin 76
Ẹ ji enyin enia
Awake, awake, all nations
- mf Ẹ ji enyin enia
Ẹ má ṣe sun titi;
f A! Imọlẹ wa nlanlà
On li o yọ de yi.
Orùn n’ imọlẹ ara,
Jesu ni ti ọkàn?
Ireti awọn baba
Yio ha de lasan? - p O de k’ ẹwọ̀n ẹ̀ṣẹ tú
O de k’ okunkun lọ;
f Ẹ yò, ijọba Jesu
O ni rọrun pupọ,
Ẹ jẹ k’ a mu ọrẹ wá
K’ a juba Ọba wa
Awọn amoye mu wá
A kì o mu wá bi? - f Je k’ a fi ọkàn wa fùn,
K’ o tẹ ‘tẹ Rẹ̀ sibẹ;
K’ a fi ohun gbogbo fun
K’ a si ṣe ifẹ Rè.
ff Ẹ yọ̀! ẹ yọ̀! ẹ tun yọ̀!
Jesu Oluwa de
F’ otoṣi at’ ọlọrọ,
Kristi Oluwa de. Amin.