Orin 75
Ji, ‘wọ, Kristian, k’ o ki orọ ayọ
Christians, awake! salute the happy morn
- f Ji, ‘wọ, Kristian, k’ o ki orọ ayọ
Ti a bi Olugbala araiye;
Dide, k’ o kọrin ifẹ Ọlọrun,
T’ awọn Angẹli nkọ n’ ijọ kini.
Lat’ ọdọ wọn n’ ihin na ti bẹrẹ;
Ihin Ọm’ Ọlọrun t’ a bi s’aiye. - f ‘Gbana l’ a ran akede Angẹli,
T’ o sọ f’ awọn Oluṣagutan, pe,
“Mo mu ‘hin rere Olugbala wá,
T’ a bi fun nyin ati gbogbo aiye,
Ọlọrun mu ‘leri Rẹ ṣẹ loni,
A bi Olugbala Krist Oluwa.” - mf Bi akede Angẹl na ti sọ tan,
Ọpọlọpọ ogun ọrun sì de;
Nwọn nkọrin ayọ̀ t’ eti kò gbọ́ ri,
Ọrun si ho fun yìn Ọlọrun pe,
“Ogo ni f’Ọlọrun l’ oke ọrun,
Alafia at’ ifẹ s’ enia.” - mf O yẹ k’ awa k’ o ma ró l’ọkàn wa,
Ife nla t’ Ọlọrun ni s’ araiye;
K’ a si ro t’ ọmọ na r’ a bi loni,
T’ o wá jiya oro agbelebu.
Ki awa si tẹle ilana Rẹ̀,
Titi a o fi de ibugbe l’ okè. - f Nigbana ‘gba ba de ọrun lọhun,
A o kọrin ayọ̀ t’ irapada;
Ogo enit’ a bì fun wa loni,
Y`o ma ràn yi wa ka titi lailai
A o ma lọrin ifẹ Rẹ̀ titi,
Ọba Angẹli, Ọba enia. Amin.