Orin 64
Iwo Onidajọ
Thou Judge of quick and dead,
- mf Iwo Onidajọ,
A fẹrẹ̀ duro na,
Pẹlu ayọ̀ tabi ẹ̀ru,
Niwaju itẹ̀ Rẹ:
Jọ pesè ọkàn wa,
Fun ọjọ nlanla nì;
p Fi ẹmi irọra kun wa
At’ ẹmi adura. - f K’a ma wo ọ̀na Rẹ,
L’ akoko aimọ̀ ni;
Nigbat’ Iwọ o sọkalẹ̀,
Ninu Ọlanla Rẹ.
Iwọ ẹni aikú
Lati da wa lẹjọ;
T’ iwọ ti ogun Baba Rẹ,
At’ ore-ọfẹ Rẹ. - mf K’ a lè ba wa bayi
Nigbọràn ọrọ Rẹ;
K’ a ma tẹti s’ohun ipè,
K’ a ma wò ọna Rẹ,
K’ a wá ìpo ayọ̀
T’ awọn oluubukun,
K’ a si ṣọra nigba diẹ,
Fun ‘simi ailopin. Amin.