Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 63

L”ẹba odo Jordani ní

On Jordan's bank the Baptists cry

Meter C.M (8.6.8.6) Bibo Jesu
  1. mf L”ẹba odo Jordani ní,
    Onibaptisi nke wipe;
    Oluwa mbọ ! Oluwa mbo!
    Ẹ gbọ ‘hin ayọ: Ọba mbo.

  2. K’ ẹ̀ṣẹ tán ni gbogbo ọkàn,
    K’ Ọlọrun ba lè bà wagbé;
    K’ a pa ilẹ ọkan wa mọ́
    Ki Alejo nla yi to de.

  3. Jesu, iwọ n’ igbala wa,
    Ẹsan, ati alabò wa;
    B’itanna l’awa ‘ba ṣegbe
    Bikoṣe t’ ore-ọfẹ Rẹ.

  4. Ṣ’ awotan awọn alaisàn,
    Gb’ẹlẹṣẹ t’o ṣubu dide;
    Tan ‘mọlẹ Rẹ ka ‘bi gbogbo,
    Mu ẹwà aiye bọ́ s’ ipò.

  5. K’ a f’ iyin f’ Ọmọ Ọlọrun,
    Bibọ̀ ẹni ‘mu ‘dande wa;
    Ẹni t’ a nsìn pẹlu Baba.
    At’ Ọlọrun Ẹmi Mimọ. Amin.