Orin 524
Ibukun ni f’okú
Hush! blessed are the dead
- p Ibukun ni f’okú,
T’o simi le jesu;
Awọn t’o gb’ ori wọn
Le okan aiya Rẹ̀. - mf Iran ‘bukun l’eyi,
Ko si ‘bòju larin;
Nwọn ri Ẹn’ Imọlẹ̀,
Ti nwọn ti fẹ lairi. - Nwọn bọ lọwọ aiye,
Pẹlu aniyàn rẹ̀;
Nwọn bọ lọwọ ewu,
T’o nrin l’ ọsan, l’oru. - mp Lori iboji wọn,
L’awa nsọkun lonik
Nwọn j’ ẹn’ ire fun wa,
T’ a kì y’o gbagbe lai. - p A k’yo gbohùn wọn mọ,
Ohùn ifẹ didun;
Lat’ oni lọ, aiye
Kì o tun mọ̀ wọn mọ. - mp Ẹnyin oninure,
Ẹ fi wa sìlẹ̀ lọ;
Ao sọkun nyin titi,
Jesu pa sọkun ri. - cr Ṣugbọn a fẹ gbóhùn
Olodumare na;
f Y’o kọ, y’o si wipe,
ff Ẹ dide, ẹ si yọ̀. Amin.