Orin 523
Awa ti gbe ọ sin, niwọ̀n l’ao daro rẹ
Thou art gone to the grave, but we will not deplore thee;
- mp Awa ti gbe ọ sin, niwọ̀n l’ao daro rẹ,
B’o tilẹ̀ jẹ nin’ okunkun l’a sin ọ si;
di Jesu rẹ ti là ọnà kanna kọja,
Fitilà ifẹ Rẹ̀ ni y’o ma ṣaju rẹ. - mp Awa ti gbe ọ sin, oju wa kò ri ọ mọ,
O kò si tun ba wa rìn laiye yi mọ;
di Ṣugbọn Jesu ti n’ apa ifẹ Rẹ̀ si ọ,
p Nj’ ẹlẹṣẹ lè kú, nitori Jesu ti kú. - mp Awa ti gbe ọ sin, o ti bọ́ agọ rẹ silẹ̀,
Bọya ẹs’ ẹmí rẹ kọ́lẹ̀ lati lọ;
f Ṣugbọn iwọ ti ji s’imọlẹ Paradise,
‘Wọ si ti ngbọ orin awọn Serafu. - mp Awa ti gbe ọ sin, niwọ̀n l’a o daro rẹ,
Ọlọrun rẹ li Olurapada rẹ,
f O gba ọ lọwọ wa, y’o si ji ọ dide,
Ikú kò n’ oro mọ, ‘tori Jesu ti kú. Amin.