Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 480

Jesu t’o wà l’oke ọrun

Jesus Thou who lives in Heaven

Meter L.M (8.8.8.8) Orin Omode
  1. mf Jesu t’o wà l’oke ọrun,
    p Sọkalẹ d’enia, o ku;
    Ninu Bibeli l’a lè ri,
    Bi On iti ma ṣe rere.

  2. O nkiri, o si nṣe rere,
    O nla ‘ju awọn afọju;
    Ọ̀pọ awọn t’o si yarọ,
    O ṣanu wọn, o si wò wọn.

  3. Jù wọnni lọ, o wi fun wọn,
    Ohun wọnni t’Ọlọrun fẹ;
    O si ṣe ẹnit’ o tutù,
    Yio si gbọ́ t’ awọn ewe.

  4. p Ṣugbọn ikú t’o kú buru,
    A fi kọ́ ‘ri agbelebu;
    Ọwọ rere t’o ṣe nkan yi,
    p Nwọn kan mọ ‘gi agbelebu.

  5. O mọ̀ b’ enia ti buru,
    O mọ b’ iyà ẹ̀ṣẹ ti ri;
    Ninu anu Jesu wipe,
    On o gbà iyà ẹ̀ṣẹ jẹ.

  6. p Bẹ l’ o kú nitori yi nà,
    cr O d’ enia, k’o ba le ku;
    Bibeli ní, o t’ ọrun wá,
    K’o lè dari ẹ̀ṣẹ ji ni.

  7. Ọlọrun o si f’ẹṣẹ jì
    Awọn t’o ronupiwada;
    Jẹ k’a ji kùtu w’oju Rẹ̀,
    K’a si gbà ẹ̀kún ore Rẹ̀. Amin.