Orin 431
Jesu ayọ̀ ọkàn gbogbo
Jesus, thou joy of loving hearts!
- f Jesu ayọ̀ ọkàn gbogbo,
Orisun ‘yè, imọlẹ wa,
di Nin’ ọpọ bukun aiye yi,
cr Laintẹlọrùn: a tọ wá. - f Otitọ Rẹ duro lailai,
p ‘Wọn gb’ awọn to kepè Ọ là;
cr Awọn ti o wá Ọ, ri Ọ.
f Bi gbogbo nin’ ohun gbogbo. - mf A tọ Ọ wò, Onjẹ Iyè,
A fẹ jẹ l’ara Rẹ titi;
A mu ninu Rẹ, Orisun,
Lati pa ongbẹ ọkàn wa. - p Ongbẹ Rẹ sa ngbẹ ọkàn wa,
Nibikibi t’o wù k’ a wà;
cr ‘Gbat’ a ba ri Ọ awa yọ̀,
f A yọ̀ nigbat’ a gbà Ọ gbọ́. - mp Jesu, wá ba wa gbe titi,
Ṣe akokò wa ni rere;
cr Le okunkun ẹ̀ṣẹ kuro,
f Tàn ‘mọlẹ̀ Rẹ mimọ́ s’aiye. Amin.