Orin 429
‘Wọ orisun ohun rere
O Fount of good, for all your love
- mf ‘Wọ orisun ohun rere,
Awa fẹ ṣe ‘fẹ rẹ;
Ohun wo l’a lè fi fun Ọ,
Ọba gbogbo aiye? - p L’aiye yi, ‘Wọ ní otoṣi,
T’o jẹ enia Rẹ:
Orukọ wọn n’Iwọ njẹwọ
Niwaju Baba Rẹ. - p ‘Gba nwọn ba nke n’ inira wọn,
Ohun Rẹ l’ awa ngbọ́;
‘Gba ba si nṣe itọju wọn,
Awa nṣe ‘tọju Rẹ. - f Jesu, má ṣai gbà ọrẹ wa,
Si f’ ibukun Rẹ si;
Ma f’ ibukun Rẹ s’ ẹbùn wa,
Fun awọn t’a nfi fun. - Fun Baba, Ọmọ at’ Ẹmi,
Ọlọrun ti a nsìn;
f Ni ki a ma fi ogo fun,
Titi aiyeraiye. Amin.