Orin 420
Olori ijọ t’ọrun
Head of the Church triumphant
- f Olori ijọ t’ọrun,
L’ayọ̀ l’a wolẹ̀ fun Ọ;
K’O to de, ijọ t’aiye,
Y’o ma kọrin bi t’ọrun,
ff A gbe ọkàn wa s’okè,
Ni ‘reti t’ o ni ‘bukun;
Awa kigbẹ, awa f’iyin
F’Ọlọrun igbala wa. - p ‘Gbat’ a wà ninu pọnju,
T’a nkọja ninu ina,
cr Orin ifẹ l’awa o kọ,
Ti o nmu wa sunmọ Ọ;
f Awa ṣapẹ, a si yọ̀,
Ninu ojurere Rẹ;
ff Ifẹ t’o sọ wa di Tirẹ,
Y’o ṣe wa ni Tirẹ lai. - p Iwọ mu awọn enia Rẹ
Kọja iṣàn idanwo;
cr A ki o bẹru wahala,
T’ori O wà nitòsi:
mf Aiye, ẹ̀ṣẹ, at’ Eṣu,
Kọjuja si wa lasan,
f L’agbara Rẹ, a o ṣẹgun,
Ao si kọ orin Mose. - mf Awa f’igbagbọ r’ogo,
T’o tun nfẹ fi wa si;
cr A kẹgàn aiye tori
Ere nla iwaju wa.
p Bi O ba si kà wa yẹ,
Awa pelu Stefen t’o kú,
f Y’o ri Ọ bi O ti duro,
Lati pè wa lọ s’ọrun. Amin.