Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 419

Ọba awọn ẹni mimọ

King of Saints, to whom the number

Meter 8.7.8.7 Ijo Olorun ni oke Orun
  1. mf Ọba awọn ẹni mimọ
    T’o mọ̀ ‘ye awọn ‘rawọ;
    Ọpọ enit’ ẹda gbagbe
    Wà yika itẹ Rẹ lai;

  2. mf ‘Mọlẹ ti kuku aiye bò,
    Ntàn ‘mọlẹ roro loke,
    Nwọn jẹ ọm’-alade lọrun,
    Ẹda gbagbe wọn laiye.

  3. mf Lala at’ ìya wọn fun Ọ,
    Ẹda kò rohin rẹ̀ mọ;
    Iwa rere wọn farasin,
    Oluwa nikan l’o mọ.

  4. p Nwọn farasin fun wa, ṣugbọn
    A kọ wọn s’iwe iye:
    Igbagbọ, adurà, suru,
    Lala on ‘jakadi wọn.

  5. mf Nwọn mọ̀ iṣura Rẹ lọhun;
    Kà wa mọ́ wọn, Oluwa,
    Nigbat’ O ba nṣiro ọṣọ,
    Ti mbẹ lara ade Rẹ. Amin.