Orin 42
Oluwa ‘kore, ‘Wọ l’a nyìn
LORD of the harvest, Thee we hail!
- mf Oluwa ‘kore, ‘Wọ l’a nyìn;
Ileri Rẹ ‘gbani kò yẹ̀;
Oriṣi ìgba sì nyipo,
Ọdọdun kun fun òre Rẹ;
Lọjọ oni, awa dupẹ;
Jẹ k’ iyin gbà ọkàn wa kan. - mf B’ akoko ‘rugbin mu wa yò;
B’ ìgba ẹ̀run nmu oru wá;
‘Gbat; ọwọ òjo ba nrinlẹ̀;
Tab’igbat’ ikore ba pón,
f ‘Wọ, Ọba wa l’a o má yiǹ;
‘Wọ l’ alakoso gbogbo wọn. - f Jù gbogbo rẹ̀ lọ, nigbati
Ọwọ Rẹ fùn ọ̀pọ ka ‘lẹ;
Gbat’ ohùn ayọ̀ gbilẹkan,
B’ẹda ti nko irè wọn jọ;
ff Awa, pẹlu y’o má yìn Ọ
Ore Rẹ ni gbogbo wa npin. - mf Oluwa ‘kore, Tirẹ ni
Ojo ti nrọ̀, orùn ti nràn;
Irugbìn ti a gbìn silẹ,
Tirẹ l’ ọgbọn ti nmu dagba;
Ọtun lẹbun Rẹ l’ ọdọdun;
Ọtun n’iyin Rẹ l’ẹnu wa. Amin.