Orin 404
Nigbat’ idanwo yi mi ka
When temptation around me roll
- mf Nigbat’ idanwo yi mi ka,
p Ti idamu aiye mu mi;
T’ọta f’ ara haǹ bi ọrẹ
Lati wa iparun fun mi;
f Oluwa jọ, má ṣ’ aìpè mi
B’o ti pè Adam nin’ ọgbá
di Pe, “Nibo l’o wa” ẹlẹṣẹ?
Ki nle bọ́ ninu ẹbi na. - f Nigbat’ Eṣu n’nu ‘tanjẹ rẹ̀
Gbe mi gori òke aiye,
T’o ni ki ntẹriba fun on,
K’ohun aiye le jẹ temi.
f Oluwa jọ, &c. - f ‘Gbat’ ogo aiye ba fẹ fi
Tulàsi mu mi rufin Rẹ;
T’o duro gangan lẹhìn mi;
Ni ileri pe, “Kò si nkan.”
f Oluwa jọ, &c. - Nigba igbẹkẹle mi
Di t’ogùn ati t’ òriṣa;
T’ ògede di adurà mi,
Ti ọfọ̀ di ajisà mi.
Oluwa jọ, &c. - Nigbati mo fẹ lati rìn
L’ adamọ̀ at’ ifẹ ‘nu mi,
T’ ọkàn mi nṣe hilàhílo,
Ti nkò gbona, ti nkò tutu,
Oluwa jọ, &c. - p Nigba mo sọnu bi aja,
L’aigbọ ifère ọdẹ mọ;
Ti nkò nireti ipada,
Ti mo npàfọ ninu ẹ̀ṣẹ.
Oluwa jọ, &c. - Nigbati kò s’ alabarò;
Ti olutunu sì jìna;
p T’ ibinujẹ, n’ ìji lile,
cr Tẹ̀ ori mi ba n’ ironu.
f Oluwa jọ, má ṣ’ aìpè mi
B’o ti pè Adam nin’ ọgbá
di Pe, “Nibo l’o wa” ẹlẹṣẹ?
Ki nle bọ́ ninu ẹbi na.