Orin 403
Eredi irọ́kẹ̀kẹ yi
What means this eager, anxious throng
- f Eredi irọ́kẹ̀kẹ yi
Ti enia ti nwọ koja?
‘Jojumọ n’iwọjọpọ na,
Eredi rẹ̀ ti nwọn nṣe bẹ?
f Nwọn dahùn lohun jẹjẹ pe,
di “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”
f Nwọn dahùn lohun jẹjẹ pe,
di “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.” - mf Tani Jesu? Eṣe ti On
Fi nmì gbogbo ilu bayi?
Ajeji Ọlọgbọn ni bi,
Ti gbogb’ enia ntọ lẹhin?
p Nwọn si tun dahun jẹjẹ pe,
cr “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”
p Nwọn si tun dahun jẹjẹ pe,
cr “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.” - Jesu, On na l’O ti kọja,
p Ọna irora wa laiye;
‘Bikibi t’O ba de, nwọn nkò
Oriṣi àrun wa ‘dọ̀ Rẹ̀;
f Afọju yọ̀, b’o ti gbọ pe,
cr “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”
f Afọju yọ̀, b’o ti gbọ pe,
cr “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.” - On sì tun de! nibikibi
Ni awa si nri ‘pasẹ̀ Rẹ̀:
O nrekọja lojude wa----
O wọle lati ba wa gbe.
f Kò ha yẹ k’a f’ayọ̀ ke pe?
cr “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”
f Kò ha yẹ k’a f’ayọ̀ ke pe?
cr “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.” - Ha ! ẹ wá enyin t’ọrùn nwọ̀!
f Gbà ‘dariji at’ ìtunu:
p Ẹnyin ti ẹ ti ṣako lọ,
cr Pada, gbà or-ọfẹ Baba;
Ẹnyin t’a danwò, abò mbẹ,
f “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”
Ẹnyin t’a danwò, abò mbẹ,
f “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.” - p Ṣugbọn b’iwọ kọ̀ ipè yi,
cr Ti o sì gàn ifẹ nla Rẹ̀,
On yio kẹ̀hinda si ọ,
Yio si kọ̀ adurà rẹ;
p “O pẹ ju” n’ igbe na y’o jẹ:---
pp “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.”
p “O pẹ ju” n’ igbe na y’o jẹ:---
pp “Jesu ti Nasarẹt’ l’o nkọja.” Amin.