Orin 388
Yọ awọn ti nṣègbe, ṣajò ẹni nkú
Rescue the perishing, care for the dying
- mf Yọ awọn ti nṣègbe, ṣajò ẹni nkú,
cr F’anu já wọn kuro ninu ẹṣẹ,
Ké f’awọn ti nṣìna, gb’ ẹni ṣubu ró,
Sọ fun wọn pe, Jesu le gbà wọn là.
p Yọ awọn ti nṣègbe, ṣajo ẹni nku,
cr Alanu ni Jesu, yio gbàla. - mf Bi nwọn o tilẹ gan, sibẹ O nduro
Lati gb’ọmọ t’o ronupiwada;
p Sa f’ itara rọ̀ wọn, si rọ̀ wọn jẹjẹ,
On o dariji, bi nwọn jẹ gbagbọ.
p Yọ awọn ti nṣègbe, &c. - mf Yọ awọn ti nṣègbe,--- iṣẹ tirẹ ni;
Oluwa yio f’agbara fun Ọ;
Fi suru rọ̀ wọn pada s’ṣna toro;
Sọ f’aṣako p’Olugbala ti ku.
p Yọ awọn ti nṣègbe, ṣajo ẹni nku,
Alanu ni Jesu, yio gbàla. Amin.