Orin 387
Ao ṣiṣẹ! ao ṣiṣẹ! ọm-Ọlọrun ni wa
To the work! To the work! we are servants of God
- f Ao ṣiṣẹ! ao ṣiṣẹ! ọm-Ọlọrun ni wa,
Jẹ k’a tẹle ipa ti Oluwa wa tọ̀;
mp K’a f’imọràn Rẹ̀ sọ agbara wa d’ọtun,
cr K’a fi gbogbo okun wa ṣiṣẹ t’a o ṣe,
mf Foriti! foriti!
cr Ma reti, ma ṣọnà,
f Titi Oluwa o fi de. - mf Ao ṣiṣẹ! ao ṣiṣẹ! bọ́ awọn t’ebi npa,
Kó awọn alarẹ̀ lọ ọ’orisun ìye!
Ninu agbelebu l’awa o ma ṣogo,
Gbati a ba nkede pe, “Ọfẹ n’Igbala.”
mf Foriti, &c. - f Ao ṣiṣẹ! ao ṣiṣẹ! gbogbo wa ni yo ṣe,
Ijọba okunkun at’irọ́ yio fọ́,
A o si gbe orukọ Jehofa leke,
N’nu orin iyin wa pe, “Ọfẹ ni’Igbala.”
mf Foriti, &c. - f Ao ṣiṣẹ! ao ṣiṣẹ! l’agbara Oluwa,
Agbada at’ ade y’o si jẹ ère wa:
‘Gbat’ ile awọn olotọ ba di tiwa,
ff Gbogbo wa o jọ hó pe, “Ọfẹ n’Igbala.”
mf Foriti! foriti!
Ma reti, ma ṣọnà,
Titi Oluwa o fi de. Amin.