Orin 379
Ọmọ Ọlọrun nlọ s’ogun
The Son of God goes forth to war
- f Ọmọ Ọlọrun nlọ s’ogun,
Lati gb’ade Ọba:
Ọpagun Rẹ̀ si nfẹ lẹlẹ,
Tal’ o ṣ’ ọmogun Rẹ̀? - mp Ẹnit o lè mu ago na,
T’ o lè bori ‘rora,
cr T’o le gbe agbelebu Rẹ̀,
f On ni Ọmogun Rẹ̀. - mf Martir ikini t’ o kọ kú,
T’o r’ọrun ṣi silẹ̀;
T’o ri Oluwa rẹ̀ loke,
T’ o pe, k’o gbà on là; - di T’ on ti ‘dariji l’ẹnu,
Ninu ‘rora ikú,
cr O bẹbẹ f’ awọn t’o npa lọ:
f Tani le ṣe bi rẹ? - ff Ẹgbẹ mimọ; awon wọnni
T’Ẹmi Mimọ bà le;
Awọn akọni mejila,
Ti kò kà iku si: - f Nwọn f’aiya ràn ida ọta,
Nwọn bá ẹranko jà;
di Nwọn f’ọrùn wọn lelẹ̀ fun ku,
Tani le ṣe bi wọn? - ff Ẹgbẹ ogun, t’ agbà, t’ ewe,
T’ọkunrin t’obinrin;
Nwọn y’itẹ́ Olugbala ká,
Nwọn wọ aṣọ funfun. - f Nwọn de oke ọrun giga,
di N’nu ‘ṣẹ́ at’ ipọnju:
p Ọlọrun fun wa l’ agbara
K’ a lè ṣe bi wọn. Amin.