Orin 378
Ọmogun Krist, dide
Soldiers of Christ, arise,
- f Ọmogun Krist, dide,
Mu hamọra nyin wọ̀:
Mu ‘pa t’Ọlọrun fi fun nyin,
Nipa ti Ọmọ Rẹ̀. - cr Gbe ‘pa Ọlọrun wọ̀,
T’ Oluwa ọmogun;
mp Ẹnit’ o gbẹkẹle Jesu,
O ju aṣẹgun lọ. - mf Ninu ipa rẹ́ nla,
On ni ki ẹ duro;
‘Tori k’ ẹ ba lè jijà na,
Ẹ di hamọra nyin. - cr Lọ lat’ ipa de ‘pa,
Ma jà, ma gbadura;
Tẹ agbara okunkun ba,
Ẹ jà, k’ ẹ si sẹgun. - Lẹhin ohun gbogbo,
Lẹhin gbogbo ija,
K’ ẹ le ṣẹgun n’ipá Kristi,
K’ ẹ si duro ṣinṣin. Amin.