Orin 368
Amọna ọka’n at’Ọgá
Leader of faithful souls, and Guide
- mf Amọna ọka’n at’Ọgá
Awọn èro l’ọna ọrun,
Jọ ba wa gbe, ani awa
T’a gbẹkẹle Iwọ nikan;
cr Iwo nikan l’a f’ọkàn sọ,
B’a ti nrìn l’ọna aiye yi. - p Alejo at’ èro l’a jẹ,
A mọ̀ p’aiye ki ṣe ‘le wa:
cr Wàwa l’a nrìn ‘lẹ òṣi yi,
L’aisimi l’a nwa oju Rẹ;
f A nyara s’ ilu wa ọrun,
Ile wa titilai l’oke. - mp Iwọ ti o rù ẹṣẹ wa,
T’ o si fi gbogbo rẹ̀ jì wa;
f Nipa Rẹ l’a nlọ si Sion,
T’a ndùna ilẹ wa ọrun;
Afin Ọba wa ologo,
O nsunmọ wa, b’a ti nkọrin. - ff Nipa imisi ifẹ Rẹ,
A mu ọna àjo wa pọ̀n;
S’ idapọ̀ Ijọ-akọbi,
A nrìn lọ si oke ọrun,
T’ awa t’ayọ̀ ni ori wa:
Lati pade Balogun wa. Amin.