Orin 367
Ẹ ma tẹ̀ siwaju, Kristian ologun
Onward Christian soldiers, marching as to war
- f Ẹ ma tẹ̀ siwaju, Kristian ologun,
Ma tẹjumọ Jesu t’o mbẹ niwaju:
Kristi Oluwa wa ni Balogun wa,
Wo! asia Rẹ̀ wà niwaju ogun,
ff Ẹ ma tẹ̀ siwaju, Kristian ologun,
Sa tẹjumọ Jesu t’o mbẹ niwaju. - f Ni orukọ Jesu, ogun Eṣu sa,
Njẹ Kristian ologun, ma nṣo si ‘ṣẹgun;
cr Ọrun apàdi mì ni hìhó iyin.
Ará, gbohùn nyin ga, gb’ orin nyin soke
ff Ẹ ma tẹ̀ siwaju, &c. - f Bi ẹgbẹ́ ogun nlá, n’ Ijọ Ọlọrun,
di Ará, a nrin l’ọna t’awọn mimọ rin:
mf A kò yà wa n’ipa, ẹgbẹ kan ni wa,
Ọkan n’ireti, l’ẹkọ́, ọ̀kan n’ifẹ.
ff Ẹ ma tẹ̀ siwaju, &c. - mp Itẹ at’ ijọba, wọnyi le parun,
Ṣugbọn Ijọ Jesu y’o wà titi lai;
cr Ọrun apadi kò le bor’ Ijọ yi,
A n’ileri Kristi, eyi kò le yẹ̀.
ff Ẹ ma tẹ̀ siwaju, &c. - f Ẹ ma ba ni kalọ, ẹnyin enia,
D’ohun nyin pọ̀ mọ wa, l’orin iṣẹgun;
cr Ogo, iyìn, ọla, fun Kristi Ọba,
Eyi ni y’o ma jẹ orin wa titì.
ff Ẹ ma tẹ̀ siwaju, Kristian ologun,
Sa tẹjumọ Jesu t’o mbẹ niwaju. Amin.