Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 336

‘Gbat aiye yi ba kọja

When this passing world is done

Meter 7.7.7.7.7.7 Ife si Olorun
  1. mf ‘Gbat aiye yi ba kọja,
    Ti orùn rẹ̀ ba si wọ̀,
    Ti a ba wọ̀ ‘nu ogo,
    T’ a bojuwò ẹ̀hin wa;
    f ‘Gbana, Oluwa, ngo mọ;
    di Bi gbese mi ti pọ̀ to.

  2. f ‘Gba mo ba de ‘b’ itẹ Rẹ,
    L’ẹwà ti kì ṣe t’emi;
    ‘Gba mo ri Ọ b’o ti ri,
    Ti mo fẹ Ọ l’ afẹtan;
    ‘Gbana Oluwa, ngo mọ̀
    di Bi gbese mi ti pọ to.

  3. f ‘Gba mba ngbọ́ orin ọrun,
    Ti ndún bi ohùn ará,
    Bi iró omi pupo:
    p T’ o si ndún b’ ohùn dùru;
    mf ‘Gbana Oluwa, ngo mọ̀
    di Bi gbese mi ti pọ to.

  4. mp Oluwa, jọ, jẹ k’a ri
    Ojiji Rẹ l’aiye yi:
    p K’a mọ̀ adùn dariji,
    Pẹlu iranwọ Ẹmi:
    cr Ki ntilẹ̀ mọ̀ l’aiye yi,
    Diẹ ninu gbèse mi.

  5. mf Ore-ọfẹ l’ o yàn mi,
    L’ o yọ mi ninu ewu;
    p Jesu l’Olugbala mi,
    Ẹmi sọ mi di mimọ́,
    cr Kọ mi, ki nfi hàn l’aiye,
    Bi gbese mi ti pọ to ! Amin.