Orin 335
Jesu Oluwa, a fẹ Ọ
We love Thee, Lord; yet not alone,
- mf Jesu Oluwa, a fẹ Ọ,
‘Tori gbogbo ẹbùn
Nt’ ọwọ Rẹ dà lat’ okè wa,
B’ ìri si gbogb’ aiye.
A yìn Ọ nitori wọnyi;
K’ iṣe fun wọn nikan,
Ni awọn ọmọ-ọdọ Rẹ,
Ṣe ngbàurà si Ọ. - p Awa fẹ Ọ, olugbala,
‘Tori ‘gba t’ a ṣako;
Iwọ pe ọkàn wa pada,
Lati t’ ọna iye.
‘Gba t’ a wà ninu òkunkun,
T’ a rì ninu ẹ̀ṣẹ:
cr ‘Wọ ran imọlẹ Rẹ si wa,
Lati f’ ona han wa. - f Baba ọrun, awa fẹ Ọ,
Nitori ‘Wọ fẹ wa;
Wọ ran Ọmọ Rẹ lati kú,
Ki awa lè n’ iyè,
mp ‘Gbat’ a wà labẹ binu Rẹ
‘Wọ fun wa n’ ireti:
cr Bi ẹ̀ṣẹ t’ a da ti pọ̀ to
Bẹ l’o dariji wa. Amin.