Orin 325
Ọm’ Ọlọrun a kò ri Ọ
We saw thee not when thou didst come
- mp Ọm’ Ọlọrun a kò ri Ọ,
Gba t’ o wá s’ aiye iku yi;
Awa kò ri ibugbe Rẹ,
Ni Nasareti ti a gàn;
f Ṣugbọn a gbagbọ p’ ẹsẹ̀ Rẹ
Ti tẹ ita rẹ̀ kakiri. - p A kò ri Ọ lori igi,
T’ enia buburu kàn Ọ mọ́;
A kò gbọ igbe Rẹ, wipe,
“Dariji wọn, tor’ aimọ̀ wọn.”
f Sibẹ, a gbagbọ pe, ‘ku Rẹ
Mì aiye, o si m’ orùn ṣu. - mf A kò duro leti boji,
Nibiti a gbe tẹ́ Ọ si;
A kò joko ‘nu yará nì,
A kò ri Ọ loju ọna.
f Ṣugbọn a gbagbọ p’ angẹli
Wipe, “?Iwọ ti ji dide.” - mf A kò r’ awọn wọnni t’o yàn,
Lati ri ‘goke-rọrun Rẹ;
cr Nwọn kọ fi iyanu wòke,
p Nwọn si f’ ẹrun dojubolẹe.
Ṣugbọn a gbagbọ pe nwọn ri Ọ.
Bi O ti noke lọ s’ọrun. - mf Iwọ njọba l’oke loni,
Wọ si mbukun awọn Tirẹ;
di Imọlẹ ogo Rẹ kò tàn
Si aginju aiye wa yi.
f Ṣugbọn, a gba ọ̀rọ Rẹ gbọ́,
Jesu, Olurapada wa. Amin.