Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 324

Tirẹ lailai l’ awa ṣe

Thine forever! God of love

Meter 7.7.7.7 Igbagbo
  1. mf Tirẹ lailai l’ awa ṣe,
    Baba, Ọlọrun ifẹ;
    cr Jẹ ka jẹ Tirẹ titi,
    Laiye yi, ati lailai.

  2. f Tirẹ lailai l’ awa ṣe,
    Ma tọju wa l’ aiye yi:
    ‘Wọ ìye, ọnà, otọ,
    Tọ́ wa si ilu ọrun.

  3. p Tirẹ lailai; --- Abukun
    L’ awọn t’ o ṣe ‘simi wọn!
    cr Olugbala, Ọrẹ wa,
    Gba ‘jà wa jà de opin.

  4. p Tirẹ lailai: --- Jesu, pa
    Awọn agútan Rẹ mọ,
    cr Labẹ ìṣọ rere Rẹ
    Ni k’o pa gbogbo wa mọ.

  5. f Tirẹ lailai:--- Aina awa
    Ni o jẹ aniyàn Rẹ;
    O ti f’ ẹ̀ṣẹ wa ji wa,
    Tọ́ wa si ibugbe Rẹ. Amin.