Orin 256
Ilẹ ayọ̀ kan wà
There is a happy land
- mf Ilẹ ayọ̀ kan wà
Ti o jinà,
Ni b’ awọn mimọ́ wà;
Nwọn nràn b’ orun;
cr A! nwọn nkọrin didùn,
Yiyẹ, l’Olugbala wa:
Ki ìyin Rẹ̀ k’ o ró,
f Yìn yìn lailai. - mf Wà silẹ ayọ̀ yi,
Wá, wá k’ a lọ;
Ẹ ṣe nṣiyemeji?
Ẹ ṣe nduro?
cr Ao wà l’alafia,
Kuro l’ ẹ̀ṣẹ at’ arò:
A o ba ọ jọba,
L’ayọ̀ lailai. - f Oju gbogbo wọn ndàn,
N’ ilẹ ayò;
p N’ ipamọ Baba wa,
Ifẹ ki ‘kú;
cr Njẹ sure lọ s’ogo,
ff Gba ade at’ ijọba;
T’ o mọ́ ju orún lọ,
Jọba titi. Amin.