Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 255

Jerusalem t’ọrun

Jerusalem on high

Meter 6.6.6.6.4.4.4.4 Oke Orun
  1. mf Jerusalem t’ọrun,
    Orin mi, ilu mi!
    Ile mi bi mba kú,
    Ẹkún ibukun mi;
    cr Ibi ayọ̀!
    Nigbawo ni,
    Ngo r’oju rẹ,
    Ọlọrun mi?

  2. mf Odi rẹ, ilu mi,
    L’ a fi pearl ṣe l’ ọ̀ṣọ́;
    f ‘Lẹ̀kun rẹ ndan fun yìn,
    Wura ni ita rẹ!
    cr Ibi ayọ̀ &c.

  3. mp Orùn ki ràn nibẹ,
    Bẹni kò s’ oṣupa;
    A kò wa iwọnyi,
    Krist n’ imọlẹ ibẹ.
    cr Ibi ayọ̀ &c.

  4. mf Nibẹ l’ Ọba mi wà,
    p T’ a dá l’ ẹbi l’ aiye;
    f Angẹli nkọrin fun,
    Nwọn si ntẹriba fun.
    cr Ibi ayọ̀ &c.

  5. Patriark’ igbani,
    Par’ ayọ wọn nibẹ;
    Awọn woli, nwọn nwò
    Ọmọ alade wọn.
    cr Ibi ayọ̀ &c.

  6. mf Nibẹ ni mo lè ri
    Awọn Apostili;
    At’ awọon akorin,
    Ti nlù harpu wura,
    cr Ibi ayọ̀ &c.

  7. mp Ni agbala wọnni,
    Ni awọn Martir wà;
    cr Nwọn wọ̀ aṣọ àla,
    Ogo bo ọgbẹ wọn.
    Ibi ayọ̀ &c.

  8. p T’ emi yi sa su mi,
    Ti mo gb’ agọ Kedar
    Ko si ‘ru yi loke:
    cr Nibẹ ni mo fẹ lọ.
    f Ibi ayọ̀ &c. Amin.