Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 232

Jesu ọrẹ ẹlẹṣẹ kú

Jesus the friend of sinners dies

Meter L.M (8.8.8.8) Ajinde Jesu
  1. p Jesu ọrẹ ẹlẹṣẹ kú,
    Awọn ọmọ Salem nsọkun:
    Okunkun bo oju ọrun,
    Iṣẹlẹ nla ṣẹ̀ lojiji.

  2. Nihin l’ a r’ anu ar’ ifẹ,
    p Ọba ogo kú f’ enia;
    Wo! ayọ̀ ki l’ a tun ri yi,
    Jesu t’ O kú tun ji dide.

  3. f Má bẹ̀ru mọ, ẹnyin mimọ́;
    Sọ bi Oluwa ti jọba;
    Kọrin b’ O ti ṣẹgun Eṣu,
    f Bi O si ti bori ikú.

  4. ff Ẹ wipe, “Ọba, wà titi,
    Iwọ t’ a bi lati gbà wa;”
    K’ ẹ bi ikú pe, “Oró rẹ dá?”
    “Iboji, iṣẹgun rẹ dà?” Amin.