Orin 216
Simi ọkàn mi, ni ireti
Be not fretful, my soul, rest in hope;
- mf Simi ọkàn mi, ni ireti;
Ma bẹ̀ru bi ọla ti le ri,
p Sa simi, iku papa l’ ọ̀na;
Iranṣẹ Ọba t’a ran si ọ. - mf Simi ọkàn mi, Jesu ti ku,
Lotọ o sì ti jinde pẹlu;
Eyi to fun ireti mi, pe
Mo ku, mo sì yè, ninu Jesu. - Simi ọkàn mi, “O ti pari;”
Jesu pari ‘ṣẹ ìgbala Rè;
Simi, a ti ṣe gbogbo rẹ̀ tan
Lẹkan lai; igbala di tirẹ. - ff Ogo fun Jesu ti O jinde!
Wọ t’a bi, t’a pa fun araiye:
Ogo funMetalọkan lailai!
Fun Baba, Ọmọ, ati Ẹmi. Amin.