Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 192

Iwọ ẹlẹṣẹ, Ẹmi nfi anu pè

The Spirit, oh, sinner, In mercy doth move

Meter 11.11.11.11 Lenti, Isoji
  1. mf Iwọ ẹlẹṣẹ, Ẹmi nfi anu pè
    Ọkàn rẹ t’o ti yigbi ninu ẹṣẹ;
    Maṣe ba Ẹmi ja, ma pẹ titi mọ,
    Ẹbẹ Ọlọrun rẹ le pari loni.

  2. f Ọmọ Ijọba, má ṣ’ ẹrú ẹṣẹ mọ;
    Gb’ ẹ̀bun Ẹmi Mimọ ati itunu:
    Má bi Ẹmi ninu, Olukọ rẹ ni, ---
    K’a ba le ṣe Olugbala rẹ logo.

  3. p Tempili d’ ibajẹ, ẹwà rẹ̀ d’ ilẹ;
    Ina pẹpẹ Ọlọrun fẹrẹ ku tan,
    Bi a fi ifẹ da, O si le tun ràn:
    Maṣe pa ‘na Ẹmi, Oluwa mbọ̀ wá. Amin.