Orin 191
Oluwa mo gbọ pe, Iwọ
Lord, I hear of showers of blessing
- f Oluwa mo gbọ pe, Iwọ
Nrọ̀ òjo ‘bukun kiri;
Itunu fun ọkàn arẹ,
Rọ̀ òjo na sori mi---
An’ emi, An’ emi,
pp Rọ̀ òjo na sori mi. - mf Má kọja, Baba Olore,
Bi ẹ̀ṣẹ mi tilẹ pọ̀;
‘Wọ le fi mi silẹ, ṣugbọn
p Jẹ k’anu Rẹ bà le mi --- An’ emi. - mf Má kọja mi, Olugbala,
Jẹ k’emi le rọ̀ mọ Ọ:
cr Emi nwá oju rere Rẹ,
p Pè mi mọ awọn t’o noè --- An’ emi. - mf Má kọja mi, Ẹmi Mimọ,
‘Wọ le laju afọju:
Ẹlẹri itoye Jesu,
p Sọ̀rọ aṣẹ na si mi --- An’ emi. - mp Mo ti sùn fọnfọn nin’ẹṣẹ,
Mo bi Ọ ninu kọja;
Aiye ti dè ọkàn mi, jọ,
p Tú mi k’o dariji mi --- An’ emi. - cr Ifẹ Ọlọrun ti ki yẹ̀;
Ẹjẹ Krist’ iyebiye;
ff Ore-ọfẹ alainiwọn;
di Gbe gbogbo rẹ̀ ga n’nu mi
--- An’ emi. - mp Má kọja mi, dariji mi,
Fà mi mọra, Oluwa;
‘Gbà o nf’ibukun f’ ẹlomi,
cr Ma’ ṣ’ ai f’ Ibukun fun mi ---
An’ emi, An’ emi,
p Má ṣ’ ai f’ Ibukun fun mi. Amin.