Orin 98
Ọlọrun Bẹtẹl, ẹniti
O God of Bethel, by whose hand
- mf Ọlọrun Bẹtẹl, ẹniti
O mbọ́ awọn Tirẹ;
Ẹnit’ o mu baba wa là
Ọjọ aiye won ja. - p A mu ẹjẹ́, at’ ẹ̀bẹ wa
Wá iwaju ‘tẹ Rẹ,
Ọlọrun awọn baba wa,
f Ma jẹ Ọlọrun wa. - Ninu idamu aiye yi,
Ma tọju wa;
Fun wa ni onjẹ ojọ wa,
At’ aṣọ t’o yẹ wa. - Na, ojiji ‘yẹ Rẹ bò wa,
Tit’ ajò wa o pin,
Ati ni ‘bugbe Baba wa,
Ọkàn wa o simi. - Iru ibukun bi eyi,
L’a mberè lọwọ Rẹ:
Iwọ o jẹ Ọlọrun wa
At’ ipin wa lailai. Amin.