Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 91

Ọjọ ati akoko nlọ

Days and moments quickly flying

Meter P.M (Irregular) Opin Odun
  1. mf Ọjọ ati akoko nlọ
    Nwọn nsún wa s’ eti ‘boji;
    p Awa fẹrẹ dubulẹ na,
    Ninu ihò ‘busun wa.

  2. mf Jesu, ‘wọ Olurapada
    Ji ọkàn t’ o ku s’ẹ̀ṣẹ;
    cr Ji gbogbo ọkan ti ntogbe,
    Lati yàn ipa iyè.

  3. mp Bi akoko ti nsunmọle,
    Jẹ k’ a rò ‘bi to a nlọ;
    Bi lati r’ayọ̀ ailopin,
    pp Tabi egbé ailopin.

  4. mf Aiye wa nlọ!
    pp Ikú de tan.
    mf Jesu, ṣọ́ wa
    pp Tit’ O fi de.
    K’ a ba Ọ gbe
    p K’ a ba Ọ kú,
    f K’ a ba Ọ jọba titi lailai.

  5. mp Aiye wa nkọja b’ojiji
    O si nfò lọ bi ‘kuku;
    cr Fun gbogbo ọun t’o kọja
    Dariji wa, mu wa gbọn.

  6. mf Kọ wa lati kà ọjọ wa,
    Lati ba ẹ̀ṣẹ wa jà;
    K’ a má ṣarẹ̀, k’ a má togbe
    Tit’ a o fi ri ‘simi.

  7. f Gbogbo wa fẹrẹ̀ duro na
    Niwaju itẹ ‘dajọ;
    ff Jesu ‘wọ t’o ṣẹgun iku
    Fi wa s’apa ọtun Rẹ.

  8. mf Aiye wa nlọ!
    pp Ikú de tan:
    Olugbala!
    mf Jọ pa wa mọ.
    K’a ba Ọ gbe,
    pp K’ a ba Ọ kú,
    f K’ a ba Ọ jọba titi lailai. Amin