Orin 87
Wà ẹnyin olotọ
Oh come, all ye faithful, joyful and triumphant!
- f Wà ẹnyin olotọ,
L’ayọ at’ iṣẹgun,
Wá kalọ, wa kalo si Bẹtlehẹm,
Wà kalọ wò o!
Ọba awọn Angẹl!
p Ẹ wá kalọ jubà Rẹ̀,
Ẹ wá kalọ jubà Rẹ̀,
f Ẹ wá k’a lọ jubà Kristi Oluwa. - Olodumare ni,
Imọlẹ Ododo,
p Kò ai korira inu Wundia;
f Ọlọrun papa ni,
Ti a bi, t’ a kò dá:
p Ẹ wá kalọ jubà Rẹ̀, &c. - f Angẹli, ẹ kọrin,
Kọrin itoye rẹ̀;
Ki gbogbo ẹda ọrun sì gberin:
Ogo f’Ọlọrun
L’ oke ọrun lọ́hun:
p Ẹ wá kalọ jubà Rẹ̀, &c, - f Nitotọ, a wolẹ
F’Ọba t’ a bi loni;
Jesu Iwọ li awa nfi ogo fun:
‘Wọ ọmọ Baba,
T’o gbé ara wa wọ̀!
p Ẹ wá kalọ jubà Rẹ̀,
Ẹ wá kalọ jubà Rẹ̀,
cr Ẹ wá kalọ juba Kristi Oluwa. Amin.