Orin 83
Ayọ̀ b’ aiye! Oluwa de
Joy to the world! The Lord is come:
- f Ayọ̀ b’ aiye! Oluwa de;
K’ aiye gbà Ọba rẹ̀;
cr Ki gbogbo ọkàn mura de
K’ iyin kọrin soke. - f Ayọ b’ aiye! Jesu jọba,
cr Ẹ je k’ a ho f’ ayọ;
Gbogbo igbẹ́, omi, òkè,
Nwọn ngberin ayọ̀ na. - mf K’ ẹ̀ṣẹ on ‘youn pin l’ aiye,
K’ ẹgún ye hù n ilẹ̀;
O de lati mu bukun ṣàn
De ‘bi t’ egún gbe de. - O f’ otọ at’ ifẹ jọba,
O jẹ k’oril’ èdè
Mọ̀ ododo ijọba Rẹ̀,
At’ ifẹ ‘yanu Rẹ̀. Amin.