Orin 79
Ọjọ ayọ̀ nlanla na de
The happy day at last has dawned
- f Ọjọ ayọ̀ nlanla na de,
Eyi t’ araiye ti nreti;
cr Nigbat’ Olugbala w’aiye
Nigbat’ a bi ninu ara. - f Oluṣagutan ni pápá
Bi nwọn ti nṣọ agutan wọn,
Ni ihin ayọ na kọ̀ bá.
Ihin bibi Olugbala. - Angel iranṣẹ Oluwa
L’ a ran si wọn, alabukun,
Pẹlu ogo t’ o tan julọ,
Lati sọ ihin ayọ̀ yi. - mp Gidigidi l’ ẹ̀ru bà wọn,
Fun ajeji iran nla yi:
f “Má bẹru” l’ ọ̀rọ iyanju
T’ o t’ ẹnu Angẹli na wá. - A bi Olugbala loni,
Kristi Oluwa aiye ni;
N’ ilu nla Dafidi l’ o wà,
p N’ ibujẹ ẹran l’ a tẹ si. - f “Ogo fun Ọlọrun” l’ orin
Ti enia y’o kọ s’ ọrun;
Fun ifẹ Rẹ̀ laini opin,
T’ o mu alafia w’ aiye. Amin.