Orin 71
Ọlọrun! Kini mo ri yi!
Great God, what do I see and hear!
- f Ọlọrun! Kini mo ri yi!
Opin de f’ ohun gbogbo!
Onidajọ araiye yọ,
O gunwa n’ itẹ ‘dajọ,
ff Ipè dùn, iboji si tú
Gbogbo awọn okù silẹ;
p Mura, lọ ko, ọkàn mí. - mf Okú ‘nu Krist y’o kọ́ jinde,
Nigba ‘pe kẹhin ba dùn;
Nwọn o lọ ko l’ awọsanma,
Nwọn o fi ayọ yí ka;
Ko s’ẹru ti y’o b’ ọkan wọn;
Oju Rẹ̀ dà imọlẹ bo,
Awọn ti o mura dé. - p Ṣugbọn ẹlẹṣẹ t’ on t’ ẹ̀ru!
Ni gbigbona ‘binu Rẹ̀,
Nwọn o dide, nwọn o si ri,
Pe, oṣé wọn kò bá mọ;
pp Ọjọ ore-ọfẹ kọja;
Nwọn ngbọ̀n niwaju ‘tẹ ‘dajọ,
Awọn ti kò mura de. - un Ọlọrun kini mo ri yi;
Opin de f’ohun gbogbo!
Onidajọ araiye yọ,
O gunwà n’ itẹ ‘dajo.
p L’ẹsẹ agbelebu, mo nwò
‘Gbat’ ohun gbogbo y’ o kọja;
cr Bayi ni mo nmura de. Amin.