Orin 595
F’ awọn Ijọ ti nsimi
From all Thy saints in warfare,
- mf F’ awọn Ijọ ti nsimi,
Awa Ijọ t’ aiye;
A f’ iyìn gbogbo fun Ọ,
Jesu Olubukun;
cr Oluwa, O ti ṣẹgun,
Ki nwọn ba le ṣẹgun;
f ‘Mọlẹ ade ogo wọn,
Lat’ ọdọ Rẹ wa ni.
St. Anderu.
mf A yin Ọ, fun ‘ranṣẹ Rẹ,
Ti o kọ j’ ipè Rẹ:
T’o mu arakọnrin rẹ̀
Wa, lati ri Kristi;
cr Pese ọkàn wa silẹ,
K’a ṣọna lọdun yi,
K’a m’ awọn ará wa wá,
Lati ri bibọ̀ Rẹ.
St. Tomasi.
mf A yìn Ọ, fun ‘ranṣẹ Rẹ,
T’ iṣiyemeji rẹ̀
F’ ẹsẹ̀ ‘gbagbọ wa mulẹ̀,
T’ o si fi ‘fẹ Rẹ hàn;
p Oluwa f’ alafia
F’ awọn ti nreti Rẹ;
cr Jẹ k’a mọ Ọ lotitọ,
L’ enia at’ Ọlọrun.
St. Stefanu.
mf A yin Ọ, fun ‘ranṣẹ Rẹ,
Ajeriku ‘kini:
Ẹni, ninu wahala,
T’o nkepe Ọlọrun;
di Oluwa, b’o ba kàn wa
Lati jiya fun Ọ,
cr L’aiye, jẹ k’a jẹri Rẹ,
L’ọrun, jẹ k’a gb’ ade.
St. Johannu Onihinrere.
mf A yin Ọ, fun ‘ranṣẹ Rẹ
L’ erekuṣu Patmo,
A yin Ọ, f’ ẹri totọ,
Ti o jẹ́ nipa Rẹ.
A yìn Ọ, fun iran na,
Ti O fihan fun wa;
mp A o fi surù duro,
K’ a le kà wa mọ wọn.
Ọjọ awọn Ọmọ wẹrẹ ti a pa.
mf A yin Ọ, f’awọn ewe,
Ajeriku mimọ;
A ṣí wọn lọwọ ogun,
Lọ sibi isimi;
Rakẹli, má sọkun mọ,
Nwọn bọ́ lọwọ ‘rora:
cr F’ ọkàn aìlẹ́tàn fun wa,
K’ a gb’ ade bi ti wọn.
Iyipada ti St. Paulu.
f A yìn Ọ, fun imọlẹ
At’ ohùn lat’ ọrun,
A si yin Ọ, fun iran,
Ti abinuku ri;
Ati fun ‘yipada rẹ̀,
A fi ogo fun Ọ
mf Jọ, tan ina Ẹmi Rẹ,
Sinu okunkun wa.
St. Mattia.
mf Oluwa, Iwọ t’ o wà,
Pẹl’ awọn t’ o pejọ;
Iwọ t’o yàn Mattia
Lati rọpo Juda:
A’ mbẹ Ọ, gbà Ijọ Rẹ
cr Lọwọ eke woli;
Rant’ ileri Rẹ, Jesu,
Pẹlu ‘jọ Rẹ dopin.
St. Marku.
f A yin Ọ fun ‘ranṣẹ Rẹ,
T’ Iwọ f’ agbara fun;
Ẹnit’ ihinrere rẹ̀
Mú orin ‘ṣẹgun dùn;
Ati n’nu ailera wa,
mf Jọ jẹ́ agbara wa;
Jẹ k’a s’ eso ninu Rẹ,
Iwọ Ajarà wa.
St. Filippi ati St. Jakọbu.
mf A nyin Ọ fun ‘ranṣẹ Rẹ,
Filippi amọna;
Ati f’ arakọnrin Rẹ,
Ṣe wa l’arakọnrin;
cr Maṣai jẹ k’ a le mọ Ọ,
Ọna, Iye, Otọ;
f K’a jẹju ko idanwo,
Titi ao fi ṣẹgun.
St. Barnaba.
mf A nyin Ọ, fun Barnaba,
Ẹnit’ ifẹ Rẹ mu
K’o kọ ‘hun aiye silẹ,
K’o wa ohun ọrun;
cr Bi aiye ti ngbilẹ si,
Ran ẹmi Rẹ si wa,
Ki itunu Rẹ totọ,
Tàn bo gbogbo aiye.
St. Johannu Baptisti.
A yin Ọ, f’ Oni-baptis,
Aṣaju Oluwa;
Elija totọ ni ‘ṣe,
Lati tùn ọ̀na ṣe.
Woli t’o ga julọ ni,
O ri owurọ Rẹ;
mf Ṣe wa l’ alabukunfun,
Ti nreti ọjọ Rẹ.
St. Peteru.
f A yin Ọ, fun’ranṣẹ Rẹ,
Ogboiya ninu wọn;
di O sebu nigba mẹta,
O ronupiwada;
mf Pẹlu awọn alufa,
Lati tọju agbo;
Si fun wọn ni igboiya
At’ itara pẹlu.
St. Jakọbu.
mf A yin Ọ, fun ‘ranṣẹ Rẹ,
Ẹniti Herod pa;
O mu ago ìyà Rẹ,
O mú ọrọ Rẹ ṣẹ;
K’ a kọ̀ iwara silẹ,
K’ a fi suru duro;
K’a kà ìyà si ayọ,
B’o ba fà wa mọ Ọ.
St. Bartolomeu.
mf A yin Ọ, fun ‘ranṣẹ Rẹ,
Ẹni olotọ nì;
Ẹnit’ oju Rẹ ti rí,
Labẹ ‘gi ọpọtọ.
cr Jọ, ṣe wa l’ alailẹtàn,
Israeli totọ;
Ki O le ma ba wa gbe,
K’ O ma bọ́ ọkàn wa.
St. Matteu.
mf A yin Ọ, fun ‘ranṣẹ Rẹ,
T’o sọ ti ibí Rẹ;
T’o kọ̀ ‘hun aiye silẹ,
T’o yàn ọna ìyà;
Jọ, da ọkàn wa nidè,
Lọwọ ifẹ owó;
cr Jẹ k’a le jẹ ipè Rẹ,
K’a nde k’a tẹle Ọ.
St. Luku.
mf A yin Ọ, f’ oniṣẹgun,
Ti Ihinrere rẹ̀,
Fi Ọ han b’ Oniṣẹgun,
At’ Abanidarò:
Jọ, f’ororo iwosan,
Si ọkàn gbogbo wa,
At’ ikunra ‘yebiye,
Kùn wa nigbagbogbo.
St. Simoni ati St. Juda.
mf F’awọn iranṣẹ Rẹ yi,
A yin, Ọ, Oluwa;
Ifẹ kanna l’o mu wọn,
Lati gb’ ọna mimọ;
cr Awa iba le jọ wọn,
Lati gbe Jesu ga:
p Ki ifẹ só wa ṣọkan,
K’a de ibi ‘simi.
IPARI (GENERAL ENDING).
f Apọstil, Woli, Martyr,
Awọn ẹgbẹ mimọ;
Nwọn ko dẹkun orin wọn,
Nwọn wọ̀ aṣọ àla;
di F’awọnyi t’o ti kọja,
A yin Ọ, Oluwa;
cr Ao tẹle ipasẹ wọn,
A o si ma sin Ọ.
ff Iyin f’ Ọlọrun Baba,
At’Ọlọrun Ọmọ,
Ọlọrun Emi Mimọ,
Mẹtalọkan Mimọ;
Awọn ti a rà pada,
Y’o tẹriba fun Ọ;
Tirẹ l’ọlá, at’ ipá,
At’ ogo, Ọlọrun. Amin.