Orin 590
‘Wọ ọ̀rọ t’o dùn julọ
O word, of words the sweetest
- mf ‘Wọ ọ̀rọ t’o dùn julọ,
Ninu eyit’ a ri
Ileri at’ imuṣẹ
Awamaridi ni:
p Nigba ẹkún at’ ayọ̀,
di ‘Yemeji at’ ẹ̀ru,
p Mo gbọ Jesu wipe, “Wa,”
Mo si lọ sọdọ Rẹ̀.
f Wa, wa sọdọ Mi,
Wa, wa sọdd Mi,
Alarẹ̀ t’ọrùn nwọ̀,
Wa ! Wa sọdọ Mi. - mp Ẹmi mi, má ṣako lọ
Kuro lọd’ Ọrẹ yi!
Sunmọ Ọ, a! sunmọ Ọ,
Ba gbé titi d’opin;
p A! alailera l’emi,
Ẹṣẹ mi papọju;
Mo nṣako nigbagbogbo,
Mo si tun pada wa.
f Wa ! wa sọdọ Mi ! &c. - mp Ma fà mi sunm’ ọdọ Rẹ,
Ki “Wa” yi ba le jẹ
Ohùn ti a fọ jẹjẹ
F’ ẹni t’o sunmọ Ọ;
Okun ati oke nla
Kì yio da mi duro
Lati dì ọwọ Rẹ mu,
Nigbat’ O wipe, “Wa.”
f Wa ! wa sọdọ Mi ! &c. Amin.