Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 581

Awa fẹ ohun aiye yi

We love all the earthly stock below

Meter C.M (8.6.8.6) Oniruru
  1. mf Awa fẹ ohun aiye yi,
    Nwọn dara l’oju wa;
    A fẹ k’a duro pẹ titi,
    Laifi wọn silẹ lọ.

  2. Nitori kini a nṣe bẹ?
    Aiye kan wà loke;
    Nibẹ l’ ẹ̀ṣẹ on buburu
    Ati ewu kò si.

  3. Aiye t’o wà loke ọrun,
    Awa iba jẹ mọ!
    Ayọ̀, ifẹ, inu rere,
    Gbogbo rẹ̀ wà nibẹ.

  4. p Ikú, o wà ni aiye yi;
    Kò si loke ọrun;
    Enia Ọlọrun wà mbẹ̀,
    Ni ayè, ni aikú.

  5. K’a ba ọ̀na ti Jesu lọ,
    Eyi t’O là fun wa;
    ff Sibi rere, sibi ‘simi,
    cr S’ ile Ọlọrun wa. Amin.